Aye Daade

AYE DAADE

Aye daade ni Naijiria

 
 
ILANA ATI ETE IFILOLE EARTH CHARTER INICIATIVE

Awon wonyi ni ete ati erongba Earth Charter iniciative.

Ete:

  1. Lati je ki awon eniyan jakejado agbaiye mo nipa Earth Charter, ati lati je ki won mo ise Pataki egbe yii.
  2. Lati je ki Earth Charter rii itewogba ni odo awon eniyan, egbe ati apapo awon orile-ede to fi mo sokan (UN).
  3. Lati je ki awon onisowo, awon osise ijoba ati ijoba gan-an funra re mo iwulo ati ilana ti Earth Charter ti pese sile fun won.
  4. Lati gbawon niyaju ati lati se atileyin fun awon Ile-iwe, Ile-iwe giga (universities), ati awon ile ijosin lati maa lo ilana ati eko Earth Chater.
  5. Lati je ki opolopo awon eniyan mo nipa eto, ilana ati ase Earth Charter

Ogbon ati ilana ati mu egbe  dagba  (ti a n pe ni Decentralized  Empowerment Ona abayo)
“Decentralized Empowerment for scalling up” ni oruko ti a fun ilana ati abajade ipade ti won se ni 2007.  Idi ti a fi se ilana yii ni lati mu ki Earth Charter dagba gan lai fowokan awon alakoso ati oludari egbe naa.  Bakan naa, lati fi aye sile fun idagbasoke ara eni. 

Fun atilehin eto yii, ati se awon ofin ati ilana ti yoo je ki o rorun fun Earth Charter lati dagba lai fi kun iye awon alakoso egbe naa.

Enikeni tabi egbe ki egbe ni o le lo  ilana Earth Charter ni agbegbe won ni ona ti o ba to ti o ba si  ye.
Awon igbimo ti yoo mojuto (Focus Areas and Task Forces)

Nibi ipade olododun ti won se ninu osu Ebibi 2008, (ECI) fowo si idasile eka mefa ti yoo mojuto awon ipin kan ti yoo si mu idagbasoke  Earth Charter wa kaakiri agbaye.  Awon eka ti a dasile yii yoo se alamojuto awon ipin wonyi:

- Awon onisowo
- Eko (Education)
- Eka irohin
- Esin
- Apapo awon orile-ede to fi imo sokan (UN)
- Awon odo

A yan awon ipin mefa yii nitori pe won fun wa ni anfaani  ati le lo awon ilana ati eto Earth Charter  ni opolopo ona ti yoo mu idagbasoke ati ilosiwaju wa. A ti se awon ise kan sile  ti yoo dabi ategun fun awon ipin ti a daruko soke yii.
A ti se eto ti yoo je ki awon eka tabi komiti yii sise takun takun ti won yoo si yoda ara won. Awon ara (ECI) ni gbogbo aye ni o si ti se ifilole eka tabi komiti yii.  Bakan naa, igbimo Earth Charter  yoo maa se ayewo ise eka (Komiti0 kookan lorekore.  Ile-ise Earth Charter  ati igbimo lapapo koni dari Eka(komiti) yii, sugbon won yoo kan maa se akiyesi ati amojuto eka naa.

O sese ki won se iranlowo fun won nigba ti won ba nilo re.  Awon oludari eka yii le ba awon egbe miiran soro tabi awon eniyan kan pato ti yoo le ranwon lowo ti won ba nilo imoran tabi itosona.

Idi Pataki ti a se da awon komiti yii sile ni pe, ilana ati eto (ECI) da le lori bi awon eniyan yoo se maa ni asepo laarin ara won ti won yoo si    tun maa se itoju ayika won. Ko rorun fun eniyan kan tabi egbe eyo kan pere ki o maa dari gbogbo Earth Charter .  Bakan naa nipe, ti egbe eyo kan soso ba fe dari gbogbo eto yii, inawo re yoo tipo ju fun egbe.

Ni tooto, Earth Charter  ti di egbe keekere ti o wa di egbe nla bayii. Olu ile ise Earth Charter  si tun wa nibe ti o n fun awon eka  naa ni amoran ati itosona.

Oludari Eka yii le e je eniyan meji si mewaa.  Idi ti a fi da eka kookan sile ni lati fi mu iyipada to peye ba gbogbo awon ipin ti a ti daruko yii. Komiti kookan yoo bere ise re nipa sise alaye lori nkan to ro pe ohun le se lori ipin ti o n ba sise.  O tun se Pataki lati se eto fun ojo-iwaju, ki won o si ni erongba fun gbogbo nkan ti won ba n se, ki won si ri  pe awon se igbelewon ki won ba le mo boya awon se dada, abi beeko.

Awon Oludari eka naa le se akojopo oruko awon eniyan ti o n ran won lowo ti o si n fun won ni omiran ati atilehin.
Gege bi abajade ipalemo fun ojo iwaaju, awon oludari ati alakoso Earth Charter  ti fowo si awon ise meji Pataki  ti a o se lai pe yii.    Bakan naa ni won fe lati ra awon ohun elo fun irohin bii awon iwe ati iwe-irohin.  Ile-ise Earth Charter  ti gba lati se awon ise meji yii.

Ile-ise Earth Charter  yoo gbe awon irohin nipa ise meji yii jade ni ori “website” wa  lai pe yii.  Awon ti o ba ni ife si ohun ti awon eka wonyi n se le kan si awon oludari eka (komiti) naa.