Aye Daade

AYE DAADE

Aye daade ni Naijiria

 
 
BI O SE LE KOPA NINU EARTH CHARTER INICIATIVE
  1. So fun awon eniyan ati awon ore re nipa eto Earth Charter ni ayika re.
  2. Fowo si eto Earth Charter, ki  o si gba egbe tabi ile-ise re ni iyanju lati kopa ninu eto won, bakan naa ni ki o gba ijoba ipinle re ni iyanju lati kopa ninu eto naa pelu.
  3. Bere tabi ki o se idasile egbe Earth Charter,  ki e si se amulo ilana naa ninu re, ibi ise re ati ni agbegbe.
  4. Darapo mo okan ninu awon eka Earth Charter  mefa ti a da sile –  Eto E ko, Awon onisowo, Eka irohin, Eto Esin, awon odo ati apapo orile-ede ti o fi imo sokan (United Nations)
  5. Fi owo sowopo pelu awon alabapin ati alabasisepo pelu Earth Charter  ati awon miiran ti won fowo si eto Earth Charter.
  6. Fi owo ati awon nkan miiran ti o se koko ran ise Earth Charter ati Earth Charter international lowo.
  7. Tele ilana egbe naa ti o mu ki egbe na dagba daa daa.

Ona pupo ni a le gba lati lo eto Earth Charter  ni ile-iwe, laarin awon onisowo, ijoba, awon onise iyoda ara-eni (NGOs), nibi ipade ajo-nla, ati nibi ipade ti o ba nise pelu awon ara ilu.  Bi apeere a le e lo:

  • Gege bi ohun elo eko ti yoo mu idagbasoke ati  oye isoro ti o dojuko eda ye awon eniyan, ati nkan ti o tumo si lati gbe igbe aye to peye.
  • Lati le pe akiyesi awon eniyan lati gbe igbe aye ifaraenijin, ifowosowopo ati irapada.
  • Gege bi ohun elo ati ilana fun ijoba lati se eto ti yoo mu ojusaaju ati aidogba kuro, ti yoo si mu ki a gbe igbeaye alaafia
  • Gege bi ilana ti yoo je ki a mo ojuse wa si ara wa ati ojuse wa si ayika wa, Pataki julo awon nkan elemi bii eranko inu igbo ati eranko inu omi,.  Bakan naa ni yoo ran wa lowo lati le ko awon ofin kan sile fun awon osise kan lati tele.
  • Lati fi se ategun fun isora-eniye laaarin orisii eniyan, ede, asa ati orisii esin lori anfaani ifowosowopo ati igbepo alafia.
  • Gege bi iwe ofin ti yoo mu ki idagbasoke ki o wa ni ayika  ati adugbo wa.
  • Gege bi ohun elo ti yoo mu ilosiwaju ti o peye wa.