Ifowosi “isakoso lori ile” (Earth Charter) lati odo awon eniyan, egbe tabi ile-ise tumo sipe won ni ife si nkan ti egbe yii duro fun ati ilana egbe naa. O tun tumo sipe won setan lati lo ilana ati ofin Earth Charter lati mu iyato ati idagbasoke ba adugbo, ayika, ilu ati orile-ede won. Ifowosi tun tumo sipe won setan lati fi ara won jin lati sise ati lati ri i pe opo awon eniyan tele ilana ati ofin ti Earth Charter ti pese sile ati lati ba awon elomiran sowopo.
Opolopo ona ni awon ti o ba fi owo si isakoso lori ile ti le se iranlowo ki won si kopa ninu eto Earth Charter. Bi apeere, awon egbe miiran le lo lati fi se atunse ilana ti won, ki won ba le maa polongo Earth Charter, won ti e le fi ilana yii sinu eto eko won.
Enikeni tabi egbe ki egbe ni o le fi owo si nkan ti Earth Charter n se (ECI) se akitiyan lati ri i pe won se iwadu ifowosi daa daa; ati pe, won tun maa n’ se adehun pelu olufowosi pe o sese ki won je ki awon eniyan mo gege bi olufowosi Earth Charter.
Iwe Adehun:
O le fowosi eto yii lori ero ayara bi asa, tabi ki o ko sinu iwe ki o si fi ranse si wa. O le lo apeere ti o wa nisale yii:
“Awa ti a fi owo si iwe yii gba a si se ileri lati fowosopo pelu Earth Charter lati mu iyato otun ati Alafia ba aye,ati lati sise ki a si polongo ilana ati ete Earth Charter”
Fun afikun, Olufowosi gbodo:
- Fi takun takun wa ilosiwaju Earth Charter, ki o si tele ilana ti o wa ni ipin kefa (VI)
- Lowosi awon eto Earth Charter, ni gbogbo ona ti won ba ti nilo iranlowo re ati igba ti o ba ye
- Se amulo awon ilana Earth Charter ninu igbeaye re ati nibi ise re.