Aye Daade

AYE DAADE

Aye daade ni Naijiria

 
 
NIPA IFOLOLE ISAKOSO LORI ILE (Ti a n’pe ni Earth Charter)

Isakoso lori ile je apapo oruko awon eniyan egbe ati ile-eko ti o n’ kopa ti o sin’ tele ilana Earth Charter.

Eto yii je eto to gboro pupo ti o si da leri awon eniyan ati egbe ti o fi ara won sile tinutinu; lara awon to n’ kopa ninu eto yii ni: Awon ile – eko giga, ljoba Orile-ede ati eka won. Unifasiti (Universities) awon ile-ise adanikan ni, ati ile-iwe. Opolopo awon egbe ni o fowo si nkan ti egbe Earth Charter n’se, ti won n’ sin wa itesiwaju egbe yii, bakan naa ni a tun ri awon eniyan kan to je pe lai kan si egbe yii tele, won kan bere si ni polongo egbe yii nitori pe won feran nkan ti egbe yii n’se.

Isakoso lori ile ni gbogbo agbaye

Egbe isakoso lori ile “Earth charter” je egbe to ni awon alakoso ati ofisi. A da eka yii sile lati pin iran yii pelu awon elomiran ati lati  so nkan ti egbe naa wa fun ati lati ro awon eniyan lati tele ofin ati ilara egbe yii, ki a ba le ni itesiwaju ati ilosiwaju egbe yii. Eka yii ni o se asoju egbe yii ni gbogbo agbaye. Ose Pataki  fun wa  lati ranti pe botile je pe egbe yii ni awon alakoso, Won fun eka kookan ni agbara ati Ore ofe lati le gbe awon igbese kan ti o se koko.

The Earth Charter Commission.

Ada egbe “Isakoso lori ile” Earth Charter sele ri Odun 1997 gege bi egbe to le da duro ti yoo si ma mojuto awon nkan ti o ni se pelu Ile aye [earth}Awon ti o se agbekale eto yii ni egbe ti a npe ni Earth Council and Green Cross International ti won si pari gbogbo akojopo, eto naa ni Odun 2000. Egbe yii ni o ni ase ti won sin se asoju egbe  isako lori ile Earth Charter ni gbogbo aye ti won ni sin gba awon Orilede miran ni iyanju lori eto naa.

Awon Alakoso Isakoso Lori ile, Earth Charter.

Awon alakoso eto yii ni o nmojuto ile-ise {secretariat} Isakoso Lori ile. Awon ni on se alakoso ati amojuto awon ofin ati ilana egbe yii. A yan awon alakoso yii lati inu awon egbe miran {groups} to n se agbateru to si ni ife si nkan ti egbe adehun lori ile n se

Ile –Ise,Isakoso lori ile Agbaye “Earth Charter International”

Ile-ise egbe yii wa ni ile-eko giga Alafia ni ilu Costa Rica (University of peace) Costa Rica ile ise yii ni o n’se atileyin gbogbo eto to nise pelu egbe yii ti won si n’ gbiyanju lati je ki awon ile eko gbogbo mo nipa eto yii. Bakan naa, ni won n’je ki awon odo, Onisowo ati awon ile esin gbogbo mo nipa eto yii nipa Irohin ati awon ofin ti a fi da egbe yi sile.
Awon Alabapin Egbe yii ni ifowo sowopo pelu awon eniyan tabi egbe to n’se agbateru ti o si setan lati tele ilana Isakoso lori ile (ECI) ni orilede won. Awon alabapin yii yoo dijo ni adehun pelu egbe yii pe won yoo ma se alamojuto ati agbateru fun gbogbo eto ati nkan ti o ba nise pelu itoju ati irohin nipa ile ati awon nkan elemi gbogbo ni orilede won. Ile-ise egbe yii ni o’se akoso gbogbo eto yi, ti yoo si ma fi iwe lrohin itoni ati awon nkan miiran to se Pataki sowo si awon alabapin won. O sese kii a ni ju eniyan kan lo tabi egbe kan lo ni Orilede kan ti yoo je alabapin. Alabapin yii yoo gba lati maa fi irohin ati awon nkan miran ti o ba se Pataki to egbe yii leti ni gbogbo igbakugba lati orilede won. Bakan na ni egbe yii naa yoo ma fi irohin ati itoni Pataki ranse si alabapin won.

Olubasowopo/Alabasisepo.

A ni awon alabasisepo ti o je pe ise ti won ni nkan se pelu eto ati liana (ECI) opolopo awon egbe yii tabi ile-ise yii ma n’je eyi ti o tobi ti o si ni asoju ni orilede miran. Awon alabasisepo yii ni adehun ti won o si fi owo bo iwe pelu egbe (ECI) lori bi awon mejeeji yoo se ran ara won lowo.

Awon Olufowosi

Olufowosi ni enikeni ti o ba ko iwe ti o si fi to egbe yii leti pe ohun n’se agbateru, ohun si ni ife si eto egbe (ECI) n’ se. Awon olufowosi yii le e je eniyan kan tabi awon egbe kan.

Ajijose Apapo ile ise (partner organizations)

Awon ajijose oniruru ile ise ni won fowosowopo pelu Asakole ile ati Earth Charter Initiative pelu inu didun ni won jijo sise ni liana Asakole ile. Awon ile ise agbaye ni won ko si bikita fun ohun to nsele ni orilede wa. Oniruru ile ise yi ti se adehun, won situn ti ko iwe adehun pelu Earth Charter International lori awon adehun wale ti a le tokasi. Awon ti won jijo se eto yi fi aramo Asakole ile pelu igbimo Earth Charter International.

Awon Olubadamoran

Awon olubadamoran egbe yii je awon eniyan ti o ti ba (ECI) sise tele ri ti won si kopa Pataki ninu idabasoke egbe naa. Ise won ni lati fun awon oludari ati alakoso amoran. Oludari (ECI) ni o ma n’ yan awon olubadamoran.

Igbimo to n’ majuto (Task Force)

A da eka yii sile lati gba awon eniyan niyanju ninu eyikeyi ninu awon wonyi: owo sise, ile-eko, esin, ile irohin agbajopo orilede ti imo won sokan ati awon odo- ile ise egbe (ECI) ni yoo yan awon oludari ti yoo maa se alakoso awon eka yii. Ile-ise yii yoosi ma se alamoju eka yii botile je pe won o ni gba ise awon eka wonyi se.

Awon Oluranlowo

Opolopo awon oluranlowo yii je awon olufowosi ti won nife si eto ti (ECI) n’se. Opo won ni o n’ fi owo, akoko ati imo sile lati fi ri ilosiwaju ati idagbasoke egbe (ECI). Awon oluranlowo le je egbe kan tabi awon eniyan kan.

Kini Isakoso lori ile? Earth Charter

Isakoso lori ile je akojopo ofin ti yoo mu ki aye lapapapo ni alafia ti yoo si tun je ki awon eniyan ko lati mojuto ile (Earth). O fe lati je ki awon eniyan mo pe a ni lati mojuto ayika wa, gbogbo eranko. Igbe pata ati gbogbo iran eniyan lapapo ati fun awon iran to n’ bo niwaju. O je iran to fun ni ireti ti a si gbodo ko pa nibe.

Isakoso lori ile Earth Charter ni se pelu bi a o se ma gbe igbe alafia ti awon eniyan yoo si maa ni idagbasoke. Ibasepo laarin awon eranko (Ecology) je okan laarin awon nkan Pataki ti egbe yii n’ mojuto. Bakan naa nkan miiran ti o tun je egbe isokoso lori ile” (Earth Charter) Logun ni mimo juto ayika wa, mimu aini ati ise kuro ni awujo wa pipin awon nkan oro wa ni orilede ni dogbandogba, bibowo fun eto elomiran, eto oselu ati alafia. Gbogbo awon nkan wonyi wo inu ara ,won, a o si le ya kan kuru lara ekeji.

Egbe isakoso lori ile Earth Charter je abajade iyori ipade igbimo po awon Orilede kan ati opo eniyan ti o wa lati Orisirisii ilu ti won si ni Orisirisi asa Imoran ati da egbe yii sile bere bi ere lati odo akojopo awon Orilede ti o se ara won ni okan (United Nations)  imoran yii rii itewogba a si da egbe naa sile fun gbogbo eniyan ni Odun 2000.

Egbe Earth Charter yii ri itewogba ni odo opolopo awon eniyan ati Orilede. Eyi ni o fun egbe naa ni ase ati ilana lati da egbe yii sile. Nkan miran ti o tunbo fun won ni okan ni iwe ase awon egbe bi egberun merin ati Ogorun marun (4500) egbe  pelu ijoba otooto fi owo si lati fun egbe naa ni ase atileyin.

Lehin ase ti won ti ri ni odo awon orisiirisii eniyan, bakanaa ni opolopo awon adajo jake jado agbaye fi ye wa pe egbe adehun lori ile Earth Charter ti n’ ni agbara pupo debi pe o ti  di iwe ase ni awon orilede kan; bi apeere egbe to n’ mojuto eto awon eniyan Declaration of Human rights egbe yii darapupo, sugbon kii se dandan fun awon ipinle ijoba ti o ba fe.

Ni iru akoko ba yii ti o je pe opolopo nkan ni o n’ yi pada egbe Earth Charter gba wa niyanju ki a ye ara wa wo ki a yan ona ti o dara ju. Ni akoko ti o je gbe pe awon orile-ede ni o n’ sowopo pelu orile-ede miiran, egbe isakoso lori ile Earth Charter gba wa ni yanju ki a ye ara wa wo ki a yan ona ti o daraju. Opo awon orile-ede ni o n’ sowopo pelu Orile-ede miiran, egbe isakoso lori ile Earth Charter rowa ki a sowopo pelu awon orile-ede miran ki a si bi ase le ran ara wa lowo. Ni akoko ti o je pe imo ati eko lori bi a o se ni ilosiwaju se Pataki, ebge yii ti ni ilana ti a le fi ni eko ati imo ti o peye.